BBC News, Yorùbá - Ìròyìn
Ìròyìn tó ṣe kókó
-
Ìjọba àpapọ̀ gbé Gómìnà 36 re ilé ẹjọ́ lórí òmìnira ijọba ìbílẹ̀, bí ìgbẹ́jọ́ ṣe lọ rèé
Adajọ Garba Lawal to lewaju igbimọ ẹlẹni meje lo gbe idajọ naa kalẹ nigba to n gbe idajọ kalẹ.
-
Wo oríṣìí àrùn tó lágbára tí ìbínú lè dá sínú àgọ́ ara èèyàn
Adari iṣẹ iwadii naa, Ọjọgbọn Daichi Shimbo salaye pe iwadii ọhun fihàn pe ibinu maa n jẹ ki ẹjẹ ṣiṣẹ ṣegeṣege.
-
Àwọn agbébọn IpoB yìnbọn pa ṣọ́jà méjì l’áyájọ́ àwọn akọni Biafra ní Aba
Ẹgbẹ agbebọn IpoB kede Ọjọbọ ọgbọn ọjọ oṣu karun un gẹgẹbi ayajọ awọn eeyan Biafra to ku nigba ogun abẹle.
-
Orin, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́Duration, 1,09
Eyi ni akojọpọ awọn ohun to n ṣẹlẹ to tayo kaakiri agbaye.
-
Kínni North Korea àti South Korea dì sínú bọ́ọ̀lù ńlá fi ránṣẹ́ sí ara wọn?
Awọn iwe ogun yii, ti wọn n pe ni “pira ” ni Korea- ni awọn orilẹede mejeeji fi sinu fere ransẹ si ara wọn lasiko ogun ọdun 1950.
-
Mo lè gbà kíyàwó mi yan àlè níta, kó ṣáà má ti kúrò nílé mi- Gaji onitiata
Gaji fi kun un pe ko si ọkunrin to pe, ko sobinrin to dara tan, o ni kaluku n gba ara wọn bẹẹ ni.
-
Wo orin Nàìjíríà tuntun ní èdè Yorùbá, àti ìgbésẹ̀ ṣísẹ̀ n tẹ̀lé tí o lè gbà fi mọ̀ọ́ ní kíákía
Kikọ orin yii ṣi le le diẹ bayii ṣugbọn lẹyin ọpọlọpọ ifọkansi o di dandan ki o ja oju ọna.
-
Wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ní ka ìbò lórílẹ̀èdè South Africa, ta ló ń borí?
Ọpọ awuyewuye lo n wọ tọ ẹgbẹ oṣelu ANC ti Aarẹ Cyril Ramaphosa n lewaju fun lọwọ bayii.
-
Fídíò, Ọ̀pọ̀ ohun aṣalóge olófùndídùn ló ń fàwọn ọmọdé ṣiṣẹ́ àìtọ́ - ìwádìí BBC tú àṣíríDuration, 4,41
Ọpọ awọn ileeṣẹ to n ṣe eroja oloorun didun yi ni wọn n sẹran pe ko si ninu iṣe awọn lati maa tẹ ẹtọ awọn ọmọde mọlẹ.
-
Wo kókó àṣeyọrí ìjọba Ààrẹ Bola Tinubu láàrin ọdún kan tó dé ipò ààrẹ
Ninu atẹjade ti Felix Morka ti i ṣe akọwe iroyin ẹgbẹ oṣelu APC fi lede ni ẹgbẹ naa ti kan saara si Aarẹ Bola Tinubu fun bi o ṣe gbaju mọ ohun to ṣe ileri fawọn araalu.
-
Ààrẹ Tinubu kéde wíwọ reluwé lọ̀fẹ̀ẹ́ fún oṣù mẹ́fà l'Abuja
Aarẹ Bola Tinubu sọ eyi nigba to n sọrọ nibi ifilọlẹ oju opopona Reluwe niluu Abuja.
-
'A ò rí oúnjẹ jẹ bíi ti àtijọ́ mọ́,' aráàlú kọminú lẹ́yìn ọdún kan tí ìjọba yọ ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù
Ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù “subsidy” ní èdè gẹ́ẹ̀sì ni owó tí ìjọba máa ń san fún àwọn la’gbàtà tó ń gbé epo wọ Nàìjíríà láti òkè òkun láti lè jẹ́ kí wọ́n máa ta epo ní àdínkù sí iye tí wọ́n ń rà á.
Ìròyìn Àkàgbádùn
-
Wo ewu tó wà nínú fífipá fún ọmọdé lóúnjẹ, pẹ̀lú bí o ṣe lè pa ọmọ
Bi ọmọ rẹ ko ba jẹun daadaa, tọ dokita awọn ọmọde lọ. Ma ṣe gbe igbesẹ to le fa iku ọmọ tabi da wahala si gbogbo mọlẹbi lọrun.
-
Wo ìpínlẹ̀ márùn-ún tí àwọn èèyàn ti kú jùlọ lẹ́yìn tí Tinubu gbàjọba
Loootọ, ijọba Tinubu ba iṣoro aisi aabo yii nilẹ ni, ṣugbọn ai-sọrọ nipa rẹ yii n kọ awọn eeyan lominu.
-
Fídíò, 'Mo fowó mi polongo ìbò fún Tinubu nírètí pé yóò pèsè iṣẹ́ yanturu, ṣùgbọ́n èmi gan ti pàdánù iṣẹ́ mi báyìí'
O ni idakeji ipese iṣẹ lọpọ yanturu ti Tinubu ṣe ileri fun Naijiria lawọn n ri.
-
Àwọn oníléètura ní Kwara fẹ̀hónú hàn lórí àfikún owó iná mọ̀nàmọ́ná, wọ́n ní ó ti fẹ́ jẹ okòòwò àwọn run
Nigba ti o n ba BBC News Yoruba sọrọ, alaga ẹgbẹ naa, Alhaji Dauda Akande sọ pe pataki ifẹhonuhan alaafia awọn ni lati jẹki ijọba mọ ipalara ati inira ti ọwọn gogo ina monamona mu de ba awọn.
-
Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ tún kọ ₦60,000 owó oṣù tíjọba fẹ́ san, wọ́n ní ₦494,000 làwọn ó gbà
Ijọba apapọ Naijiria, apapọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ati akojọpọ awọn ileeṣẹ aladani, ni wọn ti jọ n ṣepade pọ lori ọrọ owo oṣu oṣiṣẹ tuntun lati lọjọ Iṣẹgun.
-
Wo ohun tó ṣokùnfà ọ̀wọ́ngógó tòmátò káàkiri Nàìjíríà
Otitọ ni pe gbogbo nnkan lo ti gbowo lori lọja lasiko yii, amọ, ọpọ lo n pariwo lori itakun ayelujara pe tomato ti wọn ju.
-
Wo àwọn ètò márùn ún tí Ààrẹ Tinubu ṣe láàrín ọdún kan lórí ipò àti bí ó ṣe kàn ọ́
Ọdún kan lẹ́yìn ìbúrawọlé fún Tinubu láti gba àkóso Nàìjíríà, àwọn ètò wo ni ààrẹ ti ṣe láti mú ìrọ̀rùn bá àwọn ọmọ Nàìjíríà?
-
Ẹni tí kò bá tì lè kópa nínú ìṣẹ̀ṣe kò yẹ nípò ọba Yorùbá - Ọba Yakoyo
Ọba alayé náà ní gbogbo ìlú ní ilẹ̀ Yorùbá ló ní ìṣẹ̀ṣe tí wọ́n fi da sílẹ̀, nítorí náà gbogbo àwọn ọba, láì fi ẹ̀sìn ṣe gbọ́dọ̀ bọ̀wọ̀ fún àṣà àti ìṣe ilẹ̀ wọn.
-
Ọmọ àti òbí mi ní láti k'ọ́wọ̀ọ́ rìn pẹ̀lú àwọn ẹran láti lè sá fún àwọn ajínigbé
Ki ṣe igba akọkọ ree ti ikọlu awọn agbebọn yoo waye nipinlẹ Niger. Ọpọlọpọ awọn araalu ni wọn ṣekupa tabi ji gbe lọ.
-
Wo ìgbésẹ̀ mẹ́ta tí ìjọba Ààrẹ̀ Tinubu gbé, ṣùgbọ́n tí ààrẹ tẹ́lẹ̀, Olusegun Obasanjo ní kò bójúmu
Aarẹ tẹlẹri naa lo sọ eyi di mimọ lopin ọsẹ to kọja yii nibi eto apero ti wọn pe ni Paul Aje Colloquium (tPAC) to waye niluu Abuja.
Ìròyìn Pàtàkì
Kọ́milẹ́kọ̀ọ́
Móríwú
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
-
Ṣé Nàìjíríà ti já sójú ọ̀nà lẹ́yìn ọdún kan Tinubu nípò Ààrẹ?
Ọdun kan Bọla Tinubu gẹgẹ bi aarẹ lorilẹede Naijiria ti sọ ọpọ sinu akoto oṣi ati iṣẹ lai mọ ibi ti wọn yoo ti ri ounjẹ to kan jẹ.
-
Wo bí wọ́n ṣe máa ń sin òkú àwọn arìnrìnàjò Hajj tó bá kú sí Mecca
Lasiko eto Hajj ọdun 2015, eeyan to le ni ẹgbẹrun meji lo ku ninu awọn arinrin-ajo Hajj lẹyin t'awọn oniṣẹ Hajj tẹ wọn pa.
-
Ṣé lóòtọ́ làwọn ẹgbẹ́ alátakò ń wá ọ̀nà àjọṣepọ̀ Obi àti Atiku láti kojú Tinubu lọ́dún 2027?
Gbogbo ajọsọ ọrọ naa ko ju bi wọn yoo ṣe sọwọpọ di ẹgbẹ kan ṣoṣo ti yoo gbe Tinubu lulẹ ni 2027 lọ.
-
Àlá témi àti ìyàwó mi lá nípa Nàìjíríà wà lára ìdí tí a fi jápa lọ sí Amẹ́ríkà - Sam Adeyemi
O ṣalaye ni kikun nigba to n ṣe ifọrọwerọ pẹlu Seun Okinbaloye nibi ti wọn ti sọrọ nipa ipa to yẹ ki awọn ọdọ ko ninu idagbasoke orilẹede Naijiria.
-
Wo àwọn ọba alayé tí wọ́n gba adé lórí wọn ní Nàíjíríà
Wo àwọn ọba alayé tí wọ́n ti gba adé lórí wọn Nàíjíríà
-
Kí ló ṣẹlẹ̀ tí ṣokóléètì àti kòkó ṣe ń fi ojoojúmọ́ gbówó lórí?
Oludasilẹ ileeṣẹ Soapery, nilẹ Gẹẹsi, Andy Knowles sọ fun BBC pe oun ti fi owo ti ileeṣẹ naa ni si ipamọ ra koko tan latari bi koko ṣe wọn to.
-
'Ó tẹ́mi lọ́rùn kí ọmọ mi lọ sílé ọkọ ju kí àwọn ajínigbé gbe lọ lọ́fẹ̀ẹ́'
Ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kẹrìnlélógún, oṣù Karùn-ún 2024 ló yẹ kí ìgbéyàwó náà wáyé àmọ́ ìjọba ti ní kí wọ́n da dúró fúnh ìgbà kan ná.
-
Ẹ gbà mí, inú ìrora ni mo wà, mi ò sì fẹ́ kú ní kékeré, Portable pariwo síta
Portable bọ sori opo ayelujara rẹ, to si fi awọn fọnran nibi to ti n gba itọju sita pẹlu alaye pe ara n ni oun, ti oun ko si fẹ ku lojiji.