BBC News, Yorùbá - Ìròyìn
Ìròyìn tó ṣe kókó
-
Iléẹjọ́ fòfin de Aminu Ado Bayero pé kó dẹ́kun pípe ara rẹ̀ ní Emir Kano, kó sì kúrò ní ààfin
Emir Sanusi II ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọba Kano, tó sì ti wà ní ààfin ìlú, bẹ́ẹ̀ náà sì ni Emir tí ìjọba yọ nípò, Ado Bayero ti wà ní ààfin Nasarawa tó wà nínú ìlú Kano bákan náà.
-
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fásiti Ajayi Crowther lu akẹgbẹ́ wọn pa nítorí fóònù, ohun tí a mọ̀ rèé
Nígbà tí BBC News Yorùbá kàn sí ààrẹ ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ Ajayi Crowther University, Ibukunoluwa Taiwo, ó ní òwúrọ̀ ọjọ́ Àbámẹ́ta ni àwọn kan wá pé òun pé akẹ́kọ̀ọ́ àwọn kan ni ẹ̀mí ti fẹ́ bọ́ lára rẹ̀.
-
Ilé ẹjọ́ tó ń gbọ́ awuyewuye lórí ètò ìdìbò ní Ododo àti Diri ló wọlé ìbò gómìnà ní Kogi àti Bayelsa
Awọn adajọ mejeeji ni eto idibo naa waye ni ilana ti ofin gbe kalẹ.
-
Àlá témi àti ìyàwó mi lá nípa Nàìjíríà wà lára ìdí tí a fi jápa lọ sí Amẹ́ríkà - Sam Adeyemi
O ṣalaye ni kikun nigba to n ṣe ifọrọwerọ pẹlu Seun Okinbaloye nibi ti wọn ti sọrọ nipa ipa to yẹ ki awọn ọdọ ko ninu idagbasoke orilẹede Naijiria.
-
Wo ẹ̀bùn márùn-ún tó ṣe pàtàkí tí o lè fún ọmọ rẹ lásìkò àyájọ́ ọjọ́ àwọn ọmọdé
Bakan naa ni ọjọ naa tun wa fun lati maa fi polongo awọn ohun to n ṣẹlẹ si wọn, lati le ṣe iranwọ nitori igbagbọ wi pe awọn ni ọjọ iwaju orileede.
-
Lórí ọ̀rọ̀ Emir Sanusi àti Ado Bayero: ‘Àwọn jàǹdùkú kan ń gbèrò àti kọlu àwọn agbègbè kan ní ìlú Kano’
Ọga ọlọpaa naa jẹ ko di mimọ pe awọn ko nii la oju silẹ lati jẹ ki wahala naa tẹsiwaju, ati pe ohunkohun tabi igbesẹ ti awọn ba gbe, ofin ati aṣẹ ile ẹjọ lawọn n tẹle.
-
Àwọn jàǹdùkú ya bo àgọ́ ọlọ́pàá l’Eko, iléṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn ọlọ́kadà ló wà nídí ẹ̀
A gbọ pe niṣe ni iro ibọn n dun lakọ-lakọ lasiko naa, eyi to ko ibẹrubojo sọkan awọn ara agbegbe ọhun, to si mu ki awọn eeyan sa asala fun ẹmi ara wọn nipa nina papa bora.
-
Èèyàn mẹ́ta jóná kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé l’Eko
Isẹlẹ naa waye ni agbegbe Mandilas, Iyana Isolo lopoona marose Oshodi-Apapa.
-
Fídíò, Nígbà tí ìjọba gbé katakata dé láti wó Landmark Beach nítorí òpópónà Lagos- Calabar àwàdà kẹríkẹrì ni mo pè é – Olùdásílẹ̀ Landmark Beach
Ọpọlọpọ ariwo lo wọ tọ igbesẹ yii lẹyin paapaajulọ nipa adanu ọrọ aje ati iṣẹ oojọ awọn eeyan to parẹ pẹlu wiwo ibudo igbafẹ etikun naa.
-
Àwọn tó kú níbi mọ́ṣáláṣí tó dàwó l’Ékòó ti di mẹ́ta
Eyi lo jade lẹyin ti alakoso eto amuṣẹṣe ileeṣẹ naa, Ọlatunde Akinsanya sọ fun BBC nibi iṣẹlẹ ọhun lọjọ Aiku, ana pe awọn ọmọde meji lo ku, nigba ti awọn marun-un farapa.
-
Wo ìgbésẹ̀ mẹ́ta tí ìjọba Ààrẹ̀ Tinubu gbé, ṣùgbọ́n tí ààrẹ tẹ́lẹ̀, Olusegun Obasanjo ní kò bójúmu
Aarẹ tẹlẹri naa lo sọ eyi di mimọ lopin ọsẹ to kọja yii nibi eto apero ti wọn pe ni Paul Aje Colloquium (tPAC) to waye niluu Abuja.
-
Fídíò, 'Mo fẹràn Daddy mi ju Mummy lọ torí wọ́n fẹ́ mú mi lọ sí Canada'Duration, 3,19
BBC Yorùbá gbàlejò àwọn ọmọde Yoruba fun ayajọ ọjọ ewe lagbaye lọdun diẹ sẹyin.
Ìròyìn Àkàgbádùn
-
Ohun tó yẹ kóo mọ̀ nípa Oke Igeti áti ọdún ifá
Oke-Igeti o je ile Ọrunmila nibi ti gbogbo awọn onifa lagbaye ti wa ma n bo ifa paapọ ati lati se iwure leẹkan lọdun.
-
Kí ló ṣẹlẹ̀ tí ṣokóléètì àti kòkó ṣe ń fi ojoojúmọ́ gbówó lórí?
Oludasilẹ ileeṣẹ Soapery, nilẹ Gẹẹsi, Andy Knowles sọ fun BBC pe oun ti fi owo ti ileeṣẹ naa ni si ipamọ ra koko tan latari bi koko ṣe wọn to.
-
Wo àwọn ọba alayé tí wọ́n gba adé lórí wọn ní Nàíjíríà
Wo àwọn ọba alayé tí wọ́n ti gba adé lórí wọn Nàíjíríà
-
Ìjọba da ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹ̀fọn tí wọ́n ti pa kádàrá rẹ̀ dà síta láti gbógun ti àìsàn ibà
Igbagbọ wa pe awọn ẹfọn naa yo doju ija kọ awọn ẹfọn to n ṣokunfa aisan iba, ti yoo si mu adinku ba aisan iba lorilẹede naa.
-
Báyìí ni Muhammadu Sanusi II ṣe padà sípò Emir Kano
Ní ọdún mẹ́rin sẹ́yìn, gómìnà Kano nígbà náà, Abdullahi Umar Ganduje yọ Muhammadu Sanusi Kejì nípò gẹ́gẹ́ bí Emir Kano fún àwọn ẹ̀sùn lóríṣiríṣi tó fi mọ́ ṣíṣe àìgbọràn sí ìjọba.
-
Banky W ṣàlàyé bó ṣe bá àrùn jẹjẹrẹ fínra àti bó ṣe rí ìwòsàn
Iroyin ni o le ni ẹgbẹrun mẹsan an eeyan to n ni arun jẹjẹrẹ awọ ara lojumọ nilẹ Amẹrika, nigba ti arun ọhun n mu ẹmi eeyan meji lọ laarin wakati kan nilẹ naa.
-
Kílódé táwọn orílẹ̀èdè kan kìí ṣe fẹ́ rí Palestine gẹ́gẹ́ bíi orílẹ̀èdè?
Awọn orilẹ-ede ti n ṣe atilẹyin dida orilẹede Palestine silẹ gbagbọ pe yoo ṣe iranlọwọ ilọsiwaju alaafia laarin Israeli ati Palestine.
-
Àwọn àgbà òṣèrè sọ èrò wọn lórí òfin t'íjọba fi de fifi oògùn owó àti sìgá mímu ṣeré nínú fíìmù
Ijọba sọ pe awọn obi, alagbatọ atawọn ti ọrọ kan nipa ere agbelewo ti n sọrọ soke lori awọn irufẹ fiimu to n jade lọwọ yii.
-
Wo agbábọ́ọ̀lù Nàìjíríà méjì míì tó ti mi àwọn nínú eré bọ́ọ̀lù àṣekágbá Europa League yàtọ̀ sí Lookman
Saaju Ademola Lookman, agbabọọlu ikọ Super Eagles meji ti mi awọn fun ẹgbẹ agbabọọlu wọn ninu idije Europa.
-
Wo orílẹ́èdè Adúláwọ̀ márùn-ún tí ètò ọrọ̀ ajé wọn tóbi àmọ́ tí òṣì àti ìṣẹ́ ń báwọn èèyàn wọn fínra
Ọ̀pọ̀ orílẹ̀ èdè ló ní gbèsè púpọ̀ lọ́rùn, ìpèníjà àwọn ohun amáyédẹrùn, ọ̀wọ́n gógó àti àìrajaja ètò ọrọ̀ ajé
-
Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ṣe àdínkù owó oṣù tí wọ́n ń bèèrè fún sí ₦497,000, ìjọba ní ₦57,000 lòun fẹ́ san
Ijọba apapọ Naijiria, apapọ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ ati akojọpọ awọn ileeṣẹ aladani, ni wọn ti jọ n ṣepade pọ lori ọrọ owo oṣu oṣiṣẹ tuntun lati lọjọ Iṣẹgun.
-
Sanyeri gbówó kalẹ̀ fẹ́ni tó bá lè fìdí rẹ̀ múlè pé ó fẹ́ f’iṣẹ́ tíátà sílẹ̀
Ninu fọnran to gbe sori ikanni Instagram rẹ, Sanyẹri sọ pe oun ko figba kankan sọ pe oun ti fi iṣẹ tiata ti gbogbo aye mọ oun mọ, ati pe awọn kan ti wọn fẹẹ dan iṣẹ Ọlọrun wo ni wọn n gbe iroyin ẹlẹjẹ kaakiri nipa oun.
Ìròyìn Pàtàkì
Kọ́milẹ́kọ̀ọ́
Móríwú
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
-
Wo oríṣìí oúnjẹ mẹwàá ́tó wọ́n jùlọ ní orílẹ́èdè Nàìjíríà báyìí
Ìwádìí fi hàn pé ìdá 150% ní ọ̀pọ̀ oúnjẹ tó jẹ́ oúnjẹ ilẹ̀ wa fi lékún láàárín ọdún kan sí àsìkò yìí.
-
Kílódé tí wọ́n fi lé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ fásítì ọmọ Nàìjíríà kan dànù ní fásítì orílẹ́èdè UK?
Lara awọn ohun ti awọn alakoso fasiti Teesside sọ ni pe awọn ko mọ-ọn-mọ le awọn akẹkọọ to wa lati Naijiria danu, bi ko ṣe ti owo naira ti ko gbewọn mọ, eyi to si n jẹ iṣoro fun wọn lati ri owo ile-ẹkọ san.
-
Wo iye àwọn tí yòó jànfàní owó ìrànwọ́ ìdókòwò ₦110bn t'ìjọba fẹ́ ṣe fáwọn ọ̀dọ́
Minisita fọrọ eto ilọsiwaju awọn ọdọ, Ọmọwe Jamila Bio Ibrahim lo sọ eyi di mimọ l’Ọjọbọ, ọsẹ yii niluu Abuja.
-
Èéfín ẹ̀rọ amúnáwá pa èèyàn méje, ará ìlú gbarata
Ìròyìn ní àwọn èèyàn náà ń ṣiṣẹ́ ní studio lálẹ́ ọjọ́ Ajé tí oorun sì gbé wọn lọ nídìí rẹ̀, tí wọn kò sì rántí pa ẹ̀rọ amúnáwá tí wọ́n tàn láti fi ṣiṣẹ́, tó sì ṣokùnfà ìjàm̀bá náà.
-
Ìwé ìròyìn UK kan ní wọ́n ti dájọ́ ẹ̀wọ̀n ogún ọdún fún Oluwo rí l'Amẹ́ríkà tórí ìwà ọ̀daràn, Kábíyèsí fèsì
Oluwo ni “awa ko nii ba wọn da si iroyin ti wọn n gbe jade yẹn, ile-ẹjọ ni awa maa n lọ to ba ti di ni iru nnkan bẹẹyẹn.''
-
''Báwọn ọ̀daràn ṣe ń pa ọlọ́pàá làjọ PENCOM tó ń rí sí owó ìfẹ̀yìntì náà ń f'ebi p'àwa ọlọ́pàá''
Awọn ọlọpaa to ti fẹyinti ọhun ni wọn ko iwọde wọn lọ si ile igbimọ aṣofin agba l'Abuja lati rawọ ẹbẹ si wọn nipa sise ofin ti yoo yọ awọn oṣiṣẹfẹyinti ọlọpaa kuro ni ajọ PENCOM to n mojuto owo ifẹyinti awọn osisẹ lorilẹ ede Naijiria.
-
Mọ̀ nípa afurasí tọkọ-taya tí àjọ NDLEA ń wá lórí ẹ̀sùn gbígbé egbòogi olóró
Atẹjade ọhun ti agbẹnusọ NDLEA, Fẹmi Babafẹmi buwọ lu jẹ ko di mimọ pe orileede India ni Kazeem Ọmọgoriọla Owoalade ti awọn eyan mọ si Abdul Qassim Adisa Balogun ati aya rẹ Rashidat Ayinkẹ Owoalade ti awọn eeyan mọ si Bọlarinwa Rashidat Ayinkẹ ti n ṣiṣẹ wọn.
-
Ẹgbẹ́ àwọn dókítà NMA sàlàyé ìdí táwọn dókítà kò fi pọ̀ mọ́ ní Nàìjíríà
’’Dokita kan ṣoṣo yoo da ẹgbẹrun mẹfa alaisan (6,000) lohun ni Naijiria, ẹgbẹta (600) eeyan ni si ni ajọ eleto ilera agbaye ni ki dokita kan ṣoṣo da lohun.